Details |
Adebesin Olatunbosun Poem
Ènìyàn n'sáré àtilà sùgbón, kìràkìtà ò dolà.
Omo adáríhurun n'sebí elédùà sùgbón, Oba òkè dáké.
Mákànjúolá òré èmi.
Ohun tí ò tó léèní yoo sékù lóla.
Ojúlópésí, ìyókù d'owó adániwáyé.
Sa ipáàre sùgbón má Sàáré àsápajúdé
Ànfàní ni'lé ayé jé, a ósì bi é bí o se ti lò.
Àkosílè èdá kii tàsé, orí eni ló'ndire.
Má gbèrò kii tenì kejì bàjé, sebí oti mo.
Ìgbìnyànjú re, Olórun mò si
Bópé bóyá, ìyókù yoo dèrò.
Mádùúró, Márèwèsì, Ìyókù d'owó eledùà
Adébésin Olátúnbòsún
Copyright © Adebesin Olatunbosun | Year Posted 2022
|